You are currently viewing Àgbéyẹ̀wò Ètò adójú-tòfò ‘ÌLERA ÈKÓ’ Ti ìjọba Gómìnà Babajide Sanwo-Olu. | Demoshood Abiola

Àgbéyẹ̀wò Ètò adójú-tòfò ‘ÌLERA ÈKÓ’ Ti ìjọba Gómìnà Babajide Sanwo-Olu. | Demoshood Abiola

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ọkàn lára àwọn ìpèníja tó ń dojú kọ àwọn Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni ṣíṣe àgbékalè Ètò ìlera tó pé yé, tó sì kún ojú òṣùwọ̀n fún àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn oúnjẹ, àlàáfíà ṣe pàtàkì fún ọmọdé àti àgbà. Ní Ìpínlẹ̀ Èkó, gẹ́gẹ́ bí á ṣe mọ pé àwọn èèyàn tó fi Èkó ṣe ibùgbé pọ̀ ju ti gbogbo ìpínlẹ̀ yókù lọ ní Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Ìjọba tó bá sì ní ìfẹ́ àwọn ọmọ ìlú rẹ̀ lọ́kàn, tí ìgbáyé-gbádùn àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ lógún, gbọ́dọ̀ mú Eto ìlera lókun-kúndùn. Tí ètò ìlera tó dára bá wà ní Ìpínlẹ̀, tí àwọn ilé ìwòsàn alábọ́dé ni àwọn irinsẹ́ láti tọ́jú àwọn aláìsàn, èyí máa dènà ikú àìtọ́jọ́ láwùjọ irúfẹ́ Ìpínlẹ̀ náà.

Pẹ̀lú ìdojúkọ tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń là kọjá nígbà dé gbà, ó ṣe pàtàkì pé kí ìjọba ìpínlẹ̀ ṣe oun tó bá yẹ, láti rí pé àwọn Mẹ̀kúnù ni àǹfààní sì Ètò Adójú tòfò Ìlera. Ìdí tí Eto Adójú tòfò ìlera fi ṣe pàtàkì ni pé, kò sì ẹniti ó máa ń tọju owó àìsàn sílè, ojojúmọ́ dẹ̀ ni àwọn èròjà ń gbówó lérí, láti ní àǹfààní sí ìtọ́jú tó dára ní àwọn ilé ìwòsàn ìjọba, eto Adójú tòfò ìlera ṣe pàtàkì.

Ìdí nìyí tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà Babajide Sanwo-Olu fi ṣe àgbékalẹ̀ Ètò Adójú tòfò Ìlera ni ìpínlè Èkó, èyí tí a mọ̀ sí ‘ÌLERA ÈKÓ’. Ìlera Èkó jẹ́ ètò tí ó ń mú ìrọ̀rùn bá gbogbo àwa olùgbé ìpínlẹ̀ eko, láti gba ìtọ́jú, àti ìwòsàn làwọn ilé ìtọ́jú aláìsàn káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó ní owó kékeré. Ètò Adójú-tòfò ìlera Èkó kò yọ ẹnìkan sílẹ̀, yálà òṣìṣẹ́ ìjọba, oníṣẹ́ ọwọ́ tàbí oníṣòwò, àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó tó fi mọ́ àwọn Aláboyún àti ìyá-lọ́mọ ló ní àǹfààní sì ÌLERA ÈKÓ. ÌLERA ÈKÓ tí mú àgbega bá Ètò ìlera ni Ìpínlẹ̀ Èkó láti ọdún 2021 tí ìjọba gómìnà Babajide Sanwo-Olu tí ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀. Ètò yìí wá ní ojúpọ̀nǹà ìjọba ṣáá ẹlẹ́ẹkẹji THEMES plus, tí Gómìnà Sanwo-Olu, láti rí pé ọwọ́jà ìjọba rere tó ń mú ìdàgbàsókè, bá gbogbo ìpínlẹ̀ Èkó tẹ̀ síwájú.

Láti rí pé Eto Adójú-tòfò ìlera Èkó rọrùn fún tolórí-tẹlẹmù ni ijoba ipinle Eko fi ríi dájú pé ìlànà ìmọ̀jìnlẹ̀ ìgbàlódé wá nínú ọ̀nà tí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ eko lè lò láti jẹ àǹfààní Ìlera Eko. Láti fi orúkọ ṣílẹ̀ ni ìrọ̀rùn, ẹ lè tẹ 6700006# láti orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yín, tàbí kí ẹ lọ sí ìkànnì appstore, kí ẹ tẹ EKOTELEMED láti gba ojú òpó tí ó máa fún yín ní àǹfààní láti fi orúkọ sílẹ, fún Ìlera Eko.

Ẹ ó nílò owó gege láti jẹ́ àǹfààní Eto Adójú-tòfò ÌLERA ÈKÓ. Ìjọba Ìpínlẹ̀ mú rọrùn fún wá láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ abo, 8500 Naira, fún ẹni kàn péré, èyí tí ẹbi tó bá ní ọmọdé merin máa san ẹgbẹrun lọ́nà ogójì láti ní àǹfààní sì àyẹ̀wò ìlera, ìtọ́jú àti ìwòsàn ni ile ìwòsàn ìjọba àti aláàdáni. Àǹfààní wá fún ẹnikẹ́ni tó bá fi orúkọ silẹ fún ìlera Èkó láti máa sán owó díẹ̀ díẹ̀ ni osoosù bẹ̀rẹ̀ láti ẹgbẹ̀rún kan, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi orúkọ sílẹ̀.

Ẹ sọ fún ẹnì kan, kí ẹnì kan sọ fún ẹnì kan wípé, Ìrọ̀rùn ti DÉ, ìlera Èkó ti mú Ìrọ̀rùn wá.

Leave a Reply